English Músá fún Yorùbá


Yorùbá jẹ́ èdè Niger-Congo pẹ̀lú àwọn bíi mílíọ́nù àádọ́ta tó ń sọọ́ ní agbègbè tó wá láti ìwọ̀-oòrùn gúsù Nàìjíríyà dé Benin àti Togo. Ààmì èdè Gẹ̀ẹ́sì lá fi máa ń kọọ́ báyìí, tí kò sì mú ìtẹ́lọ́rùn púpọ̀ wá.

Nàìjíríyà jẹ́ orílẹ̀-èdè tó tóbi tó sì kún fún oríṣiríṣi èèyàn. Ó ní ju igba mílíọ́nù èèyàn lọ, pẹlú èdè tó tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta. Gbígba gbogbo onírúurú èdè yìí mọ́ra papọ̀ sójú kan jẹ́ ìgbèníjà fún àìmọye ọdún. Nítorí ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú àwọn òyìnbó, èdè Gẹ̀ẹ́sì ni èdè tí ìjọba fọwọ́ sí láti lò, nítorínáà ó jẹ́ oun tí a faramọ́ pé ààmì èdè Gẹ̀ẹ́sì yìí náà làá fi máa kọ àwọn èdè Nàìjíríyà. Ṣùgbọ́n èyí ò tíì móríyá púpọ̀: ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èdè Nàìjíríyà ló ní ohùn tí alúfábẹ́ẹ́tì Gẹ̀ẹ́sì ò ní ààmì fún.

Ní bíi 1928, àwọn oníṣẹ́ ìwádìí kan ṣẹ̀dá Álúfábẹ́ẹ́tì Ilẹ̀ Adúláwọ̀ kan tó ní ààmì mẹ́rìndínlógójì (36). Ní 1978, irú mìíì tún tẹ̀lé e wáyé tí a pè ní Alúfábẹ́ẹ̀tì Ìwádìí Áfríkà tó ní ààmì ọgọ́ta (nígbà tó parí), àti òmíì lọ́dún díẹ̀ síi tí a pè ní Alúfábẹ́tì Gbogbogbò-Nàìjíríya tó ní àwọn ààmí mẹ́tàlélọ́gbọ̀n (33) péré fún àwọn èdè Nàìjíríyà. Ṣùgbọ́n kò sí ìkankan nínú àwọn álúfábẹ́ẹ́tì yìí ti a lò yíká tàbí tí àwọn àtẹ ìtẹ̀wé kọ̀mpútà tàbí ààmì kọ̀mpútà rànlọ́wọ́.

Pẹ̀lú ìgbéjáde Unicode ní ààrín ọgọ́rùún ọdún sẹ́yìn, a ti wá ní tó àwọn lẹ́tà egbèje dín-láàádọ́ta (1350) nínú Alúfábẹ́ẹ́tì Látínì tí a Fẹ̀lójú, tí ó sì ní ìgbọ̀nwọ́ yíká. Ṣùgbọ́n ó yanilẹ́nu pé àwọn èdè Nàìjíríyà kan ò ní lẹ́tà níbẹ̀. Fún àpẹẹre, àwọn fáwẹ́lì tó ní ààmì lábẹ́ àti ààmì ohùn lórí.

Bóyá nítoríi ìtàn abaninínújẹ́ yìí, àti ìfẹ́ inú láti kọ èdè nínú álúfábẹ́ẹ́tì èdè àwọn òyìnbó amúnisìn, ọ̀pọ̀ nínú àwọn èdè Nàìjíríyà ló ti wá ní álúfábẹ́ẹ́tì tiwọn: Tafi fún Hausa, Ndebe fún Igbo, Odùduwà fún Yorùbá, àti Adlam fún Fúlàní, fún àpẹẹrẹ. Ewu ibẹ̀ ni pé a tún máa pín

Músá jẹ́ ọ̀nà àbáyọ. Ó le kọ gbogbo àwọn èdè Nàìíríyà (àti Gẹ̀ẹ́sì!) pẹ̀lú álúfábẹ́ẹ́tì tí a dá lórí ìrísí mẹ́wàá (10) ìpìlẹ̀ péré, lórí àtẹ ìtẹ̀wé kọ̀mpútà ọlọ́mọ ogún. Nínú Músá, irú lẹ́tà kannáà ló máa dúró fún ìró ohùn kannáà — kò rí bẹ́ẹ̀ báyìí — tí ẹni tó ń sọ Hausa á fi le ka orúkọ Igbo láìní wàhálà, bí kò tiẹ̀ le sọọ́. Músá lè kọ àwọn ìró ohùn tí a nílò, kìí tún gbóríyìn fún ni tí a kò bá fi ààmì síbi tó yẹ, èyì tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́ báyìí, tí àwọn èèyàn ń ṣọ̀lẹ, tí wọn ń kọ̀ láti fi ààmì sórí ọ̀rọ̀ wọn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Músá kìí ṣe ọ̀nà àbáyọ̀ fún orílẹ̀ èdè Nàìjíríyà nìkan, kìí ṣá kúkú jẹ oun tí a jogún fún wa láti ọ̀dọ̀ òyìnbó amúnisìn àtijọ́.

Kí ni ìdí tí Músá fi dára jùlọ fún Yorùbá

  1. Lọ́nà tó yàtọ̀ sí álúfábẹ́ẹ́tì Róòmù, Músá ní gbogbo lẹ́tà tí a nílò fún Yorùbá; a kò nílò àwọn lẹ́tà àsopọ̀ bíi gb tàbí ng, a kò nílò àwọn lẹ́tà alámì ìsàlẹ̀ bíi ẹ ọ ṣ, kò sì ní ìdí láti fún àwọn lẹ́tà Róòmù ní ara bíi p tàbí j.
  2. Músá ní àwọn lẹ́tà ọ̀tọ̀tọ̀ fún kọ́nsónántì n (tó jẹ́ ẹ̀dà l tó wá ṣaájú àwọn fáwẹ́ẹ́lì àránmúpè), àti èyí àránmúpè onísílébù, àti èyí tó jẹ́ fáwẹ́lì àránmúpè. Èyí méjì ìgbẹ̀yìn yìí ń lo lẹ́tà kannáà , ṣùgbọ́n kò sí èdèàìyedè: tó bá tẹ̀lé fáwẹ́ẹ́lì, á sọọ́ di àránmúpè; bí bẹ́ẹ̀kọ́, á di aránmúpè onísílébù. A máa ń kọ àránmúpè onísílébù gẹ́gẹ́ bíi sílébù kíkún, pẹ̀lú kọ́nsónántì àránmúpè (m n ng) níwájú fáwẹ́lì ọ̀hún láti kọ pípè ojúlówó rẹ̀ jáde.
  3. Ààmì ohùn jẹ́ oun tí a máa ń fi sí ọ̀rọ̀, láì fún wa ní wàhálà títẹ̀jáde (iye ìgbà kannáà la máa tẹ̀ẹ́). Èyí jẹ́ nítorípé gbogbo fáwẹ́ẹ̀lì Músá — bíi gbogbo lẹ́tà Músá ní gbogbo èdè — ni ó nílò títẹ̀ lẹ́ẹ̀mejì péré. Ṣùgbọ́n èyí tó ṣe pàtàkì jùlọ ni pé nínú Músá, kò sí ìdí kankan láti má fi ààmì ohùn síi nítorí ọlẹ. Gbogbo fáwẹ́lì òkè ni a máa ń kọ lókè, gbogbo fáwẹ́ẹ̀lì ààmì ohùn ìsàlẹ̀ ni wọ́n ní ààmì ilẹ̀ lórí wọn. Gbogbo fáwẹ́ẹ̀lì ààmì ohùn àárín ni a kìí fi ààmì kankan sí.
  4. Èdè Yorùbá máa ń lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ òkèèrè, láti inú èdè Gẹ̀ẹ́sì àti láti inú àwọn èdè mìíràn. Àwọn òǹkọ̀wé ẹ̀ náà á fẹ́ l àwọn orúkọ òkèèrè àwọn èèyàn àti agbègbè. Gbogbo ẹ̀ la lè kọ pẹ̀lú Músá, bóyá pẹ̀lú ààmì òmíràn. Fún àpẹẹrẹ, èyí ni orúkọ Nàìjíríyà tí a kọ ní Yorùbá pẹ̀lú ààmì Njoya àti ti Gẹ̀ẹ́sì pẹ̀lú ààmì Dushan.

     

  5. Ju bó ṣe jẹ́ èdè alámi ohùn, Yorùbá tún jẹ́ èdè to dálérí fáwẹ́ẹ̀lì, èyí tó fi yàtọ̀ sí àwọn èdè lárúbáwá mìíràn tó dálérí kọ́nsónántì bíi Hausa, Amharic tàbí Arabic. Ní Yorùbá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rọ̀ ló bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú fáwẹ́ẹ̀lì; ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rọ̀ kékèké mìíì ló sì wà tó kàn jẹ́ fáwẹ́ẹ̀lì nìkan ni wọ́n. Fáwẹ́ẹ̀lì mẹ́jọ péré ọ̀tọ̀tọ̀ ló wà (pẹ̀lú àwọn aránmúpè onísílébù), ṣùgbọ́n ààmì ohùn ló ń gbé wọn yọ, àti ríránmúpè, àti gígùn. (Àwọn èdè Niger-Congo tó kù, àti àwọn tó dálérí fáwẹ́ẹ̀lì, ni wọn ń ya fáwẹ́ẹ̀lì sọ́tọ̀ sí ẹ̀rọ̀ àti líle. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ló sì ní ìdàpọ̀ fáwẹ́ẹ̀lì).

    Àwọn oun tó mú Músá dára jù:

  6. Músá jẹ́ oun alára: bí ìkọsílẹ̀ yìí ṣe rí lára lẹ́tà náà ni ohùn dídún ẹ̀ ṣe rí. Àwọn fáwẹ́ẹ̀lì kúrú nígbà tí àwọn kọ́nsónáǹtì ga. Àwọn fáwẹ́ẹ̀lì roboto ní lẹ́tà roboto, àwọn ohùn asínnupè àti aládinupè ní ìdí roboto, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ: àwọn ohùn tó jọra wọn ní lẹ́tà tó jọra wọn (kò dàbíi c k q, fún àpẹẹrẹ). Èyí mú Músá rọrùn láti kọ́.
  7. Músá jẹ́ gbogbo àgbáyé: ó fẹ́ẹ̀ le kọ gbogbo èdè tó wà nílé ayé tán. Ó ní tó igba lẹ́tà, gbogbo wọn sì ní ohùn kannáà ní gbogbo èdè. Ṣùgbọ́n orí ẹ̀rọ ìtẹ̀wé tí gbogbo ayé ń lò náà la ti máa ń kọọ́ pẹ̀lú bọ́tìní ogún péré.
  8. A lè kọ Yorùbá pẹ̀lú Odùduwà, Igbo pẹ̀lú Ndebe, Fulani pẹ̀lú Adlam, Hausa pẹ̀lú Tafi, à†i bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, bí wọ́n ṣe ń ṣe ní India — gbogbo èdè ibẹ̀ ló ní ààmì tí wọ́n fi máa ń kọ wọ́n. Ṣùgbọ́n níbẹ̀, kò sí ẹni tó lè ka orúkọ ẹnìkejì, a ò lè pín ẹ̀rọ ìtẹ̀wé kọ̀mpútà lò, a kàn máa kọ gbogbo nǹkan lédè òyìnbó ni, tàbí lọ́nà ti Róòmù tí kò dáa. Ó sàn kí á pín álúfábẹ́ẹ̀tì kan lò, báà bá tiẹ̀ le ka èdè ara wa.
  9. Músá jẹ́ èdè tó lo fónẹ́tíkì (a ń pèé ní olóhùngooro): a máa ń kọ oun tí a bá sọ lẹ́nu, kìí ṣe oun tí a bá rò pé a ń sọ. Fún àpẹẹrẹ ní Yorùbá, a máa ń kọ an àti ọn, bó tiẹ̀ ṣe pé nǹkankannáà ni wọ́n nítorípé wọ́n dún yàtọ̀ síra wọn. Oun tí a fẹ́ ni láti kọ ọ̀rọ̀ bí ẹni pé ẹni tó ń kàá kò mọ àwọn ìlànà ọ̀tọ́gíráfì èdè náà ni. A yàn láti kọ́ àwọn lẹ́ta, dípò àwọn ìlànà òfin.
  10. Álúfábẹ́ẹ̀tì Músá àti àtẹ ìtẹ̀wé ẹ̀ lè tún kọ nọ́mbà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rọ̀ ìṣirò, àti àwọn fọ́múlà — kò sí nọ́mbà ọ̀tọ̀tọ̀, kò sì sí èdèàìyedè.
  11. Músá máa ń kọ ìró ohùn pẹ̀lú ààmì ìdánudúró, kí a má baà nílò àti lo ìlà lábẹ́ ọ̀rọ̀, ààmì ìkọ̀wé oríṣiríṣi, tàbí emoji. Eléyìí ṣe pàtàkì nítorípé àwọn ọ̀nà ìkọ̀wé tí kìí kọ ìró ohùn máa ń fààyè gba daigilọ́síà láàárín ọ̀rọ̀ tí a sọ àti èyí tí a kọ sílẹ̀, èyí tí a fẹ̀ mú kúrò. A fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa lè kọ ohun tí wọ́n bá ń sọ: ìró ohùn — kìí ṣe ìtumọ̀, orísun ọ̀rọ̀, tàbí mọfọ́lọ́jì (ìtumọ̀ inú gírámà).
  12. Músá ń ṣiṣẹ́ dáadáa nínú ayélujára: Músá ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Unicode tórípé a ti tẹ̀ẹ́ sínú Ààyè Oun Ìlò Ara ẹni (ní E000-G2E3). Oríṣiríṣi ààmì ìkọ̀wé ló wà, àti àtẹ ìwòran fún púpọ̀ nínú àwọn àtẹ ìkàwé ayélujára, àti àtẹ ìtẹ̀wé onírúurú bíi àfọwọ́tẹ̀, toríi kọ̀mpútà, àti ti jìnàréré. A sì tún ní oríṣiríṣi àwọn èèyàn tó ń bá wa yí àwọn oun tí a kọ sílẹ̀ dà láti Yorùbá sí Músá.
  13. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà ìkọ̀wé ni a ṣẹ̀dá ẹ̀ fún àwọn tó ń sọ èdè yìí gẹ́gẹ́ bí èdè abínibí wọn, tí wọn á ti kọ́ láti kàá láti ìgbà kékeré wọn. Bó ṣe yẹ kó rí nìyí! Ṣùgbọ́n gbogbo ọ̀nà ìkọ̀wé ló ní àwọn mìíràn tó yẹ kó lè lòó — àwọn àgbàlagbà tí wọn ò mọ̀wéé kà púpọ̀ tó bí wọ́n ṣe fẹ́ (àwọn ọmọ Yorùbá nílùú òyìnbó, fún àpẹẹrẹ), àwọn tó ń sọ irúfẹ́ èdè tí kìí ṣe ti gbogbogbò, awọn tó mọ̀ọ́-kọ-mọ̀ọ́-kà ní èdè mìíràn (ní Nàìjíríyà tàbí tòkèèrè) tó ń kọ́ sísọ Yorùbá nígbà tí wọ́n ń kọ́ kíkọ Yorùbá. Àti àwọn tí wọ ò nílò láti kà tàbí kọ Yorùbá ṣùgbọ́n tí wọ́n nílò láti dá àwọn orúkọ tàbí ọ̀rọ̀ Yorùbá mọ̀ àti láti le sọ wọ́n. Ẹ̀ka ìgbẹ̀yìn yìí kún fún àwọn bíi arìnrìnàjò onírúurú, olùṣàkóso ìjọba, àwọn ẹgbẹ́ àgbáyé, tàbí ibi iṣẹ́, àti àwọn aṣàkóso ìwé àti oun mèremère ìtàn. A ṣẹ̀dá músá pẹ̀lú wọn lọ́kàn pẹ̀lú.

    Àwọn oun tí kò dáa tó nípa Músá:

  14. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, kò sí àwùjọ èdè kankan tó ń lo Músá; àwọn èèyàn díèdíè tó fẹ́ràn ẹ̀ ló ń lòó, a ò sì mọ̀ọ́ káàkiri dáadáa. Musa Academy ló ń polongo ẹ̀ káàkiri àgbáyé, ṣugbọ́n Yorùbá máa jẹ́ ìkan lára àwọn èdè tó ń lòó.
  15. Ó máa ń ṣẹlẹ̀ kí á rí ìdíwọ́ díẹ̀ tí a bá ń lo Músá pẹ̀lú kọ̀mpútà. Bó dilẹ̀ jẹ́ pé a ní àwọn ọ̀nà díẹ̀ láti mú ìṣòro yìí lọ, ìṣòro yìí ò ní lọ tán títí tí a ó fi ní àwọn ènìyàn púpọ̀ tó ń lo ọ̀nà ìkọ̀wé yìí. (Irú àwọn ìkùnsínú yìí náà la ṣì ní nígbà tí a bá ń lo álúfábẹ́ẹ̀tì Róòmù àti Unicode!)
  16. Músá kò ní ìbáṣepọ̀ àtijọ́wá tàbí ti ará ilé pẹ̀lú Yorùbá, Nigeria, tàbí Africa. A kò dáa sílẹ̀ láti jẹ́ ohùn fún ìdánimọ̀ fún orílẹ̀-èdè, ẹ̀sìn, tàbí òṣèlú. Ó jẹ́ oun tí a fi ń fi pàtàkì ẹ̀kọ́ àti mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà hàn, àǹfàní fún sísọ̀rọ̀ lọ́nà tó yé ni, àti iyì tó wà nínú mímú gbogbo èdè tí a bá lè mú wọ inú ọjọ́ iwájú.

A mọ̀ pé kí a yí ọ̀nà tí a fi ń kọ ọ̀rọ̀ padà pátápátá jẹ́ ohun tó lè ka ni láyà, ó sì mú ìgbèníjà púpọ̀ wá tí kò ní nǹkankan láti ṣe pẹ̀lú ọ̀nà ìkọ̀wé tàbí ìmọ̀ ẹ̀rọ: ipa òṣèlú ibẹ̀, ètò ẹ̀kọ́, bí a ṣẹ ń kọ ìtàn àti lítíréṣọ̀ sílẹ̀, àti oríṣiríṣi nǹkan mìíràn. Ó fi yé wa pé láti ṣe ìyípadà yìí kìí ṣe oun tí àwùjọ èèyàn gbọdọ̀ ṣe ní yẹpẹrẹ.

Ṣùgbọ́n àwọn èdè máa ń pààrọ̀ ààmì ìkọ̀wé wọn: ó tó bíi 25 tó ti yípadà láàrín ọgọ́rùú ọdún sẹ́yìn; ó sì tó bíi mẹ́ta láàárín ọdún tó kọjá (Kazakh, Ède Mongolia àti Inuktut). Díẹ̀ lára àwọn ìyípadà yìí ni ó ti di kẹ́sẹjárí, papàá jùlọ níbi tí ààmì ìkọ̀wé Ṣaìnísì tàbí abjad Lárúbáwá fi di yíyípadà sí álúfábẹ́ẹ̀tì ti Látínì (ìkìlọ̀ fún àwọn tó fẹ́ kí á fẹ Ajami lójú) bíi Ède Fiẹ́tínámù, Tọ́kì, tàbí Màlé. Àwọn mìíràn, bí àwọn tí a ń yí padà láti Sirillíkì sí Látìnì, ní àtubọ̀tán tó lọ́wọ́rọ́.

Kíkọ Yorùbá ní Músá

Álúfábẹ́ẹ̀tì Yorùbá tí a ń lò lọ́wọ́lọ́wọ́, tí a ń lò ní Nàìjíríyà àti Togo, máa ń lo àkọsílẹ̀ oníbejì gb, àti ààmì kan kékeré tí a máa ń kọ sábẹ́ ẹ ọ ṣ láti fi fáwẹ́èlì alanupè tàbí ohùn asínnupè hàn. Ní Benin, a ní álúfábẹ́ètì orílẹ̀ èdè tó máa ń kọ awọn ìró ohùn yìí bíi ɛ ɔ sh. Méjì nínú àwọn lẹ́tà méjì tó ṣẹ́kù ní ọ̀nà pípè tó yàtọ̀: p ni ó dúró fún kp (bí wọ́n ṣe ń kọọ́ ní Benin), j sì dúró fún oun tí a pè jáde lókè ẹnu bíi ty ní Họ́ngarì. Láfikún, ààmì òkè ´, ààmì ìsàlẹ̀ `, ààmì makrọ́nì ¯, ààmì igun ìsàlẹ̀ ^, àti ààmì igun òkè ˇ ni a ń lò láti fi ààmì ohùn hàn.

Ààmì ìkọ̀wé Músá ní àwọn lẹ́tà tó sọnù yìí. Àwọn fáwẹ́ẹ̀lì ọ̀hún nìwọ̀nyí:

i u
e o
e̩ (ɛ) o̩ (ɔ)
a

A ní àránmúpè fún gbogbo àwọn fáwẹ́èlì máràrún, bótiẹ̀ ṣe pé ọn àti an jẹ́ irú kannáà:

   
in un
   
en on
 
an

Lọ́nà oní Sílébù, a máa ń fi àsopọ̀ àránmúpè hàn ní gígé sí méjì (ààbọ̀) lórí àti sábẹ́ fáwẹ́ẹ̀lì.

Àránmúpè onísílébù míì náà tún wà èyí tí ó máa ń farajọ kọ́nsónántì tó bá tẹ̀lée. Ní Músá, a máa ń kọọ́ gẹ́gẹ́ bíi sílébù kíkún, pẹ̀lú fáwẹ́ẹ̀lì àránmúpè , tí kọ́nsónántì àránmúpè ṣaájú ẹ̀: m níwájú b f m, n ṣaájú t d s n l r j sh y, àti ng níwájú gbogbo àwọn ìyókù, tó fi mọ́ fáwẹ́ẹ̀lì àti ìdákẹ́jẹ́ ráńpẹ́. Ọ̀nà ìkọ̀wé ti Róòmù tí a ń lò lọ́wọ́lọ́wọ́ kìí fi ìfarapẹ́ra hàn, nítoríáà, ènìyàn nílò láti mọ àwọn òfin ibẹ̀. Ṣùgbọ́n ní Músá, a máa ń kọọ́ jáde ni dípò òfin. Bí a ṣe ń kọọ́ nísìnyìí tún máa ń rú ni lójú nígbà tí aránmúpè onísílébù bá tẹ̀lé fáwẹ́ẹ̀lì, tó jẹ́ ìdí tí a fi ń kọọ́ ní .

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ Yorùbá ló bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lu fáwẹ́ẹ̀lì. Àwọn fáwẹ́ẹ̀lì yìí ló sì máa ń farajọra pẹ̀lú fáwẹ́ẹ̀lì ìgbẹ̀yìn ọ̀rọ̀ tó ṣaájú ẹ̀, nígbà míì pẹ̀lú ìpàrójẹ. Àtubọ̀tán ọ̀rọ̀ yìí ni Músá máa ń kọ; a máa pa ọ̀rọ̀ méjèèjì pọ̀.

Láàárín ọ̀rọ̀ kan, a máa ń ya fáwẹ́ẹ̀lì méjì sọ́tọ̀ nínu Músá́ pẹ̀lú àlàfo , a sì máa ń pe méjèèjì lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ bíi sílébù méjì. Ṣùgbọ́n fáwẹ́ẹ̀lì tí a sọ di méjì — tó máa ń jẹ́ àtubọ̀tán ìfarajọra nígbà púpọ̀ — pọ̀ nínú èdè, èyí tó máa ń di fáwẹ́ẹ̀lì gígùn tó máa ń ní ìró ohùn méjì lórí. Bí a ṣe ń kọọ́ lọ́wọ́ báyìí ni láti kọ fáwẹ́ẹ̀lì náà lẹ́ẹ̀mijì, ṣùgbọ́n Músá máa ń kọ ìkejì gẹ́gẹ́ bíi ààmì gígùn . Ìró ohùn kejì ni a fi ààmì kan sórí ẹ̀ lọ́nà gígùn.

Àwọn kọ́nsónáǹtì

p (kp) t k
b gb d j g
f s s̩ (sh) h
m l n ng
w r y

Gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà tí a fi ń kọ ọ̀rọ̀ nísinsìnyí ṣe rí, Músá máa ń kọ l gẹ́gẹ́ bíi n níwájú fáwẹ́ẹ̀lì aránmúpè, bí a ṣe ń pèé. Ṣùgbọ̀n yàtọ̀ sí bí a ṣe ń kọọ́ báyìí, Músá tún máa ń kọ àwọn ọ̀rọ̀ tó tẹ̀lé yìí gẹ́gẹ́ bíi aránmúpè.

Ìró ohùn

A máa ń kọ Yorùbá pẹ̀lú ìró Onísílébù, a sì máa ń kọ ìró ohùn pẹ̀lú ààmì:

Abánikọ̀rọ̀

Abánikọ̀rọ̀ yìí jẹ́ oun èlò láti kọ Yorùbá ní Músá. Ó máa ń gba ni láàyè lati yí oun tí a ti kọ ní Yorùbá tẹ́lẹ̀ ní álúfábẹ́ẹ̀tì Róòmù sí ti Músá. Láfikún, ó máa ń fún ni ní àtẹ ìtẹ̀wé mẹ́ta ọ̀tọ̀tọ̀ láti tẹ lẹ́tà wọlé àti láti ṣàtúnṣe oun tí a tẹ̀.

Abánikọ̀rọ̀

Àpẹẹrẹ

Nísìnyí tí o ti mọ̀ nípa àwọn lẹ́tà yìí, kílódé tí oò gbìyànjú láti ka díẹ̀ lára àwọn Yorùbá tí a kọ pẹ̀lú Músá?


O dájú dánu, o ò mo̩ e̩sán me̩sàn-án

Àkọsílẹ̀ Oníbejì

Láti fi bí Yorùbá ṣe rí tí a bá kọọ́ ní Músá hàn, èyí ni àkọsílẹ̀ kan tí a kọ lọnà méjì: ẹ̀ka kìnní àkọsílẹ̀ nípa Èdè Yorùbá lórí Wikipedia, lákọ̀ọ́kọ́ ní Músá, àti lẹ́yìnọ̀rẹyìn ní ọ̀nà ìkọ̀wé Róòmù, fún àwifé. A ṣẹ̀dá ti Músá nípa Abánikọ̀rọ̀ tí a ti dárúkọ lókè, a sì fihàn nínu ààmì Sílébù ti Njoya Musa. Àwọn orúkọ àjèjì wà ní ààmì ìkọsílẹ̀ Álúfábẹ́ẹ̀tì Dushan Musa. Nítorípé èmi ò mọ Yorùbá, mi ò lè fi ààmì ohùn síi. Nítorínáà, mo ti lo oun tí a pè ní ayánrọ̀ tí kò pójú ìwọ̀n. Mo mọ̀ pè àṣìṣe díè máa wà níbẹ̀ nítoríi bí mi ò ṣe gbọ́ èdè tó, àti nígbà mìíràn nítorí àṣiṣe lásán. Mo tọrọ àforíjìn.



Èdè Yorùbá: Ni èdè tí ó ṣàkójọ pọ̀ gbogbo kú oótu o-ò-jíire bí, níapá ìwọ̀ Oòrùn ilẹ̀ Nàìjíríà, tí a bá wo èdè Yorùbá, àwọn onímọ̀ pín èdè náà sábẹ́ ẹ̀yà Kwa nínú ẹbí èdè Niger-Congo. Wọ́n tún fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ẹ̀yà Kwa yìí ló wọ́pọ̀ jùlọ ní sísọ, ní ìwọ̀ oòrùn aláwọ̀ dúdú fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún. Àwọn onímọ̀ èdè kan tilẹ̀ ti fi ìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀ pé láti orírun kan náà ni àwọn èdè bí Yorùbá, Kru, Banle, Twi, Ga, Ewe, Fon, Edo, Nupe, Igbo, Idoma, Efik àti Ijaw ti bẹ̀rẹ̀ sí yapa gẹ́gẹ́ bi èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó dúró láti bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọ̀dún sẹ́yìn. ọ̀kan pàtàkì lára àwọn èdè orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni èdè Yorùbá. Àwọn ìpínlẹ̀ tí a ti lè rí àwọn olùsọ èdè Yorùbá nílẹ̀ Nàìjíríà ni ìpínlẹ̀ ẹdó, ìpínlẹ̀ Òndó, ìpínlẹ̀ ọ̀ṣun, ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́, ìpínlẹ̀ Èkó, àti ìpínlẹ̀ Ògùn. ẹ̀wẹ̀ a tún rí àwọn orílẹ̀-èdè míràn bí Tógò apá kan ní Gúúsù ilẹ̀ Amẹ́ríkà bí i Cuba, Brasil, Haiti, Ghana, Sierra Leone, United Kingdom àti Trinidad, gbogbo orílẹ̀-èdè tí a dárúkọ wọ̀nyí, yàtọ̀ sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, òwò ẹrú ni ó gbé àwọn ẹ̀yà Yorùbá dé ibẹ.

Níbíyìí tún ni àpẹẹrẹ iṣẹ́ Yorùbá mìíràn tí a kọ ní Músá — èyí ni ewì Ìtẹ́tísí láti ọwọ́ Kọ́lá Túbọ̀sún:

































© 2002-2024 The Musa Academy musa@musa.bet 02apr24